Ìpadàbọ̀ bẹ̀rẹ̀ lónìí!

Ìpadàbọ̀ jẹ́ àkókò pàtàkì tí ó ṣáájú Kérésìmesì fún wa láti ronú lórí ohun tí ìbí Jésù túmọ̀ sí fún wa.

Ohunkóhun tí o bá ń gbé wọ àkókò yìí, yálà ayọ̀ ni, ìdààmú, ọ̀fọ̀, tàbí ìrètí, kò sí àkókò tí ó dára ju èyí lọ láti gbé gbogbo rẹ̀ tọ Ọlọ́run wá.

Atọ́nà Ìwé Mímọ́ jẹ́ ọ̀nà kan láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan, ìwọ yóò gba ẹ̀kọ́ kúkúrú, àṣàrò, àti àdúrà. Ní òní BibleProject ń bẹ̀rẹ̀ Ìpadàbọ̀ fún wa.

Ní òní, wá bí o ṣe wà, kí o sì ya ìṣẹ́jú márùn-ún sọ́tọ̀ láti sinmi pẹ̀lú Ọlọ́run.

Ṣí Atọ́nà Ìwé-Mímọ́

Share this post:

Ẹ ṣeun gan-an fún bí ẹ ṣe kópa nínú Oṣù Bíbélì Àgbáyé!

Ẹ ṣeun gan-an fún bí ẹ ṣe kópa nínú Oṣù Bíbélì Àgbáyé!

O pinnu láti ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún for 30 days … o ò sì dá ṣe é.

O darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn Ẹgbẹ̀rún mẹ́ta tó lé ní tí wọ́n ń bá Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lò ní oṣù kọkànlá.

Ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn tí o dara pọ̀ mọ́ ni Pamela.

Nígbà tí Pamela ń dàgbà, ó ní ìrora púpọ̀, ọgbẹ́ ọkàn, àti ọ̀pọ̀ ìbéèrè nípa ẹni tí ó jẹ́. Ìgbà yẹn ni ó yíjú sí Bíbélì tí ó sì rí Ètò kan nípa ìdánimọ̀.

“Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi hàn mí pé Jésù ti fún mi ní ìdánimọ̀ mi. Ṣùgbọ́n èmi ni mi ò tíì ṣàwárí rẹ̀. Òtítọ́ yìí ló yí ohun gbogbo padà.”

Pamela, MEXICO

Oṣù Bíbélì Àgbáyé lè máa parí, ṣùgbọ́n Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kì í ṣe fún àkókò kan ṣoṣo. Ó yẹ kó jẹ́ apá kan nínu ìgbésí ayé ojoojúmọ́ rẹ, bí o ṣe ń jẹ́ kí Òtítọ́ yí ọ padà, bí ó ṣe yí ìgbésí ayé Pamela padà.

Nítorí náà, máa tẹ̀síwájú! Tẹ̀síwájú láti máa ní ìbáṣepọ̀ pẹ́lú Ọlọ́run nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ Rẹ̀, kí o sì wo ohun tí yóò ṣe…

Ṣí Ohun Èlò Bíbélì

Share this post:

Ní ìgbà tí ìrètí dàbí ohun tí kò ṣeé ṣe, Ọlọ́run pàdé Álísìì.

Alice-Story-Header-2026-11

Ìkìlọ̀ nípa àkóónú: ìtàn tí ó tẹ̀lé e ní àwọn kókó nípa ṣíṣe ara ẹni léṣe àti ìsoríkọ́ tí ó lè kó ìdààmú bá àwọn òǹkàwé kan.

Ní ìgbà tí ìrètí dàbí ohun tí kò ṣeé ṣe, Ọlọ́run pàdé Álísìì.

Ní ìgbà tí Álísìì pé ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún, ó rí ara rẹ̀ nínú ìgbèkùn ìrora àti àdánù, ìsoríkọ́ àti ìdáwà sì borí rẹ̀.

Pẹ̀lú bí ipó àìnírètí rẹ̀ ṣe ń peléke sí i, ní alẹ́ ọjọ́ kan ó pinnu láti gba ẹ̀mí ara rẹ̀. Ìgbà náà ni ohun tí kò ṣeé ṣàlàyé ṣẹlẹ̀.

Ní etí ìlékè fèrèsé ilé alájà gíga gogoro tí ó ń gbé, ẹ̀fúùfù líle kan fẹ́ lójijì, ó sì mú u ṣubú sẹ́yìn wọ inú yàrá rẹ̀ dípò kí ó ṣubú síwájú.

Bí ó ṣe dùbúlẹ̀ lórí ilẹ̀, tí ẹnu yà á, tí ó sì ń sọkún, Álísìì gba àtẹ̀jíṣẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ aládùúgbò rẹ̀ tí ó ń pè é sí ilé ìjọsìn. Ó gbà láti lọ, ibẹ̀ sì ni ó ti kọ́kọ́ ṣàwárí Ohun Èlò Bíbélì.

Ní ìgbà tí ìrètí dàbí ohun tí kò ṣeé ṣe, Ọlọ́run pàdé Álísìì.

Ó bẹ̀rẹ̀ Ètò Bíbélì kan. Nípasẹ̀ rẹ̀, ó rí ìrètí, ó sì fi ayé rẹ̀ fún Jésù.

Lónìí, Álísìì ń ṣẹ̀dá, ó sì ń ṣe àtẹ̀jáde àwọn Ètò Bíbélì gẹ́gẹ́ bí alábàáṣiṣẹ́pọ̀ YouVersion nípasẹ̀ ohun èlò kan náà tí ó fi Jésù hàn án. Kì í ṣe pé ìrètí kún inú rẹ̀ nìkan—ó tún ń tan án kálẹ̀.

Ṣé o mọ ẹnìkan ní àyíká rẹ tí ó níílò Ọlọ́run gidigidi? Fi Ohun-èlò Bíbélì hàn án, kí o sì bèèrè pé kí Ọlọ́rùn fi ìrètí kún inú wọn.

Share this post:

Àwọn ọmọdé ń nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run…

Àwọn ọmọdé ń nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run…

Ní ìgbà tí Jóṣúà lọ sí ìsìn Bíbélì kan fún àwọn ọmọdé, ó ṣàwárí Ohun-èlò Bíbélì fún Àwọn Ọmọdé. Ìgbà náà ni ohun gbogbo yí padà.

A bí í ní afọ́jú, ó kọ́ pé òun kàn lè fetí sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kò sì pẹ́ tí ó fi nífẹ̀ẹ́ sí Bíbélì.

Ní ìgbà tí bàbá rẹ̀ rí ayọ̀ ìyípadà tí ó wà nínú ọmọ rẹ̀, ó lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì, ó sì fi ayé rẹ̀ fún Krístì ní ọjọ́ náà gan-an. Láìpẹ́ lẹ́yìn náà, gbogbo ìdílé wọn gba Jésù.

Ní báyìí, Jóṣúà àti àwọn òbí rẹ̀ ń sìn nínú ṣọ́ọ̀ṣì agbègbè wọn, wọ́n ń ka Bíbélì papọ̀ lójoojúmọ́, wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ láti pín Ohun-èlò Bíbélì fún Àwọn Ọmọdé fún àwọn ẹlòmíràn.

Ṣé o fẹ́ kí àwọn ọmọdé tí ó wà ní àyíká rẹ nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? Fún Oṣù Bíbélì Àgbáyé, wo Ohun-èlò Bíbélì fún Àwọn Ọmọdé, kí o sì fi Ìwé Mímọ́ hàn àwọn ọmọdé nípasẹ̀ àwọn ìtàn Bíbélì tí wọ́n lè kópa nínú rẹ̀. ⬇️

Ṣí Ohun èlò Bíbélì fún Àwọn Ọmọdé

Share this post:

Òtítọ́ ń wá ọ̀nà dé àwọn ibi tí a kò retí.

George ń kà ìwé mímọ́ fún àwọn ọmọ kékeré

Pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ó lé ní 700,000, Kibera ní Kẹ́ńyà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn agbègbè òtòṣì tí ó tóbi jùlọ ní àgbáyé.

Ìgbésí ayé níbí lè dà bí ohun tí kò ṣeé ṣe. Ojoojúmọ́ ní ń mú àwọn ìṣòro rẹ̀ wá—láti rí oúnjẹ jẹ, láti tọ́jú ìdílé, àti kí ènìyàn kàn wulẹ̀ tẹ̀síwájú. Ọ̀pọ̀ ni kò rí ọ̀nà àbáyọ.

Òtítọ́ ń wá ọ̀nà dé àwọn ibi tí a kò retí.

“Àwọn ènìyàn ń ṣe àfẹ́rí ìrètí gidigidi. Wọ́n níílò Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n wọn kò ní ẹnikẹ́ni tí ó lè sọ fún wọn. Ìdí nìyìí tí mo yàn láti wà níbí.”

George, Kẹ́ńyà

George dá ilé ẹ̀kọ́ kan sílẹ̀ ní Kibera láti ran àwọn ọmọdé lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́. Ó sì tún rí ọ̀nà láti fún wọn ní ohun mìíràn—àǹfààní sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nípasẹ̀ Ohun-èlò Bíbélì Ṣékélé.

A ṣe àkànṣe ohun-èlò yìí tí kò níílò ìkànnì ayélujára fún àwọn agbègbè bíi Kibera, kí àwọn ènìyàn lè rí Bíbélì kà kí wọ́n sì jinlẹ̀ nínú rẹ̀ ní ibikíbi, ní ìgbàkúùgbà.

Òtítọ́ ń wá ọ̀nà dé àwọn ibi tí a kò retí.

Ní báyìí, George ń pín Ohun-èlò Bíbélì Ṣékélé fún gbogbo ẹni tí ó wà ní àyíká rẹ̀, ó sì ń yí gbogbo àwùjọ rẹ̀ padà!

“Mo ń pín Bíbélì fún gbogbo ẹni tí mo mọ̀. Ní báyìí ó ń tàn ká ibi gbogbo. Àwùjọ ń yípadà nítorí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.”

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń dé orílẹ̀-èdè gbogbo, ẹ̀yà gbogbo, àti ènìyàn gbogbo. Bí o ṣe ń ṣe àjọyọ̀ ohun tí Ọlọ́run ń ṣe ní gbogbo àgbáyé, ronú lórí Ìfihàn 7.

Ka Ìfihàn 7

Share this post: